Kinni Aisan Kansa Omu (Breast Cancer)

Close Window  

Awon oun ti o diropo mo ara won, ninu ara lati di odindi enia, awon wonyi ni a n’pe ni seeli (cells). Seeli yi ni eya ara ti o kere julo. Nigbati awon eyi ti won gbarajo lati di omu ba bere sii bi omo ti won si n’po si, ju iye ti ara fe tabi ti o niilo, ni igba yi ni a ma n’so wipe eniyan ni Kansa Omu.

Aworan ti a nwo loke yi, fi apere bi omu ti aisan Kansa ba sese bere si baja se ma nri. E o se akiyesi wipe ko si abawon kankan lara omu yi ti a le fi oju lasan ri. Sibe sibe, aisan yi ti gberiso ninu omu ti a wo yi. Iba ohun ti alaisan yi se akiyesi ni wipe “kooko” kan wa ninu omu yi fun bi ojo melo kan ti ko si dun un!

Ohun ti o je ki aisan Kansa Omu yi buru jayi ni wipe, ni igbati akoba ba de si ara awon seeli omu wonyi, won a gba agbara lati tan kuro ni inu omu ti akoba yi ti bere, eje ati omi ara a si gbe won lo si awon eya ara yoku bi arin egungun, opolo, fuku, ati edo. Agbara yi ni a n’pe ni metasitasisi (metastasis). Idi niyi ti aisan Kansa Omu se buru jayi.

Kinni ounfa Aisan Kansa Omu

Nigbati enia ba se akiyesi aisan yi lara, orisirisi ero lotunlosi lo ma gba okan alaisan ati awon ore tabi molebi re. Abi ounje kan ti o je ni tabi eyi ti ko je? Boya omo gunfe si omu yi ni? Tabi asasi ni? Elo miran tile le ro wipe lati ibe isekuse ni enia ti nko aisan yi. Ko ri be ara! Ko si idi kan soso ti a mo ti o nfa aisan yi. Amo, awon ohun kan wa ti won le jeki aisan yi tete se enikan ju enikeji. Awon ohun wonyi ni:

 • Ojo ori – Aisan yi a ma wopo lara awon agbalagba ju awon omode lo

 • Aisan obinrin ni aisan yi. O sese ki okunrin nii, amo ko wopo

 • Aisan yi a maja ninu awon iran kankan. Ti molebi kan ba ti ni aisan yi, yala Iya, Egbon, Aburo, tabi Omo, ewu re a po si fun awon molebi yoku

 • Bi eniyan ba ti ni aisan yi ni omu kan ri, o sese wipe ki o tun ni ni omu keji lojo iwaju

 • Aisan yi a ma po lara awon obirin ti won ko ba tete bere ikan osu, ti o pe ki won to se abiyamo, tabi ti won ko ri omo bi

 • Lilo awon ogun ti o ni Oestrogen ninu lati feto si omo bibi, tabi lati se oge nigba ti agba ba nde si ara, tabi lati fi wa omo bi.

 • Bi eniyan ba ti sanra si, paapa lehin ti o ba ti da nkan osu ni sise duro, tabi bi o ba ti ga si, beni o sese si wipe ki aisan yi ba enia ja.

 • Awon aisan omu miran ti ki i se Kansa a ma huwa bi alasosile fun kansa omu.

Afowofa ko ni ipa kankan ko ninu boya eniyan le ni aisan yi. Ki ise aisan ti a nko lati ara eniyan. A ni idaniloju wipe aisan yi ki i se ebi alaisan.

Bawo ni eniyan se le mo boya oun ni aisan yi

Ohun ti alaisan yio koko se akiyesi re ni KOKO ti yio wu sinu omu ti ko si ni dun alaisan. Koko yi a dabi ewo tabi ibiti kokoro ti ta eniyan, a mo ko ni dun ni. Bi obirin ba se akiyesi koko ninu omu re, o se pataki wipe ki o lo si odo Dokita fun itoju. Dokita nikan ni o le so pato irufe arun ti koko yi le je. Ni igba ti aisan yi ba sese bere, omu ti o ni aisan kansa ninu ko ki n’yato si awon omu yoku – e wo apere aworan kinni ti a fi han. Ko ni fa ara riro, iba, iko, otutu, ailejeun, tabi igbe gburu. Ko si ni di lilo kabo eda lowo, beni o n’se ose fun ara sibe. Eleyi ni o je ki aisan yi buru jayi.

Nigba miran, aisan yi yio bere bi ogbe ori omu. Ogbe yi a si ma tan lai jinna.

Ni ara obirin miran, ohun ti won a koko se akiyesi ni wipe ori dede ibiti ori omu ti otun ati osi yato si ara won. Igbamiran ewe, ori omu a ma fa sinu eran ara omu yoku.

Aworan oke yi fi aisan kansa omu ti o ti wora jinna han. E o ri wipe ori omu yi ti fa wole. Bi e ba wo dada, e o se akiyesi koko ti o wu si oke ori omu obirin yi. Ki aisan yi to wora to bayi ni o ye ki alaisan ti ma wa si ile iwosan!

Bi a ba fi sile lehin ti o ti wu bayi, a gba gbogbo omu kan debi wipe alaisan a tile ro wipe o ti lo ni, nigbati won ko ba le da omu yato si aisan mo! Lehin eyi, yi o wa di ogbe ti kii jina. Ogbe yi a ma se omi ara, oyun ati eje; a si ma ni eniyan lara pupo.

Bi eniyan ko ba ko ibi ara si aisan yi, aisan na yio bere si tan ka gbogbo ara, inira a wa bere. Awon inira ti a le ri ni wonyi:

 1. Eyin tabi ibadi riro. Eleyi le won alaisan lara debi wipe ko tile ni le gbe ese. A si bere si to tabi ya igbe si ara

 2. Iko egebe tabi eleje. Alaisan ko ni le mikan, won a si ma fi gbogbo agbara mi.

 3. Ikun alaisan le wu, ki omi ara gbarajo sinu re.

 4. Ese si le ro

Nje aisan yi se tete damo

O sese ki a tete mo bi eniyan ba ni aisan yi lara. Ona ti a si le gba ni lati ma ye omu eni wo ni ilana ti a se alaye si inu iwe tire (Breast Awareness). Ilana yi ni wipe, ni ekankan losu, obirin yio se ayewo omu re finnifinni fun awon ohun bi koko, awo yiyi, eda lati ori omu, ati be be lo. Obirin si ni lati bamu dokita re mule wipe ki dokita ko ohun bi ohun yio ti se ma se ayewo yi. Dokita papa yio si ma ye omu yi wo lekan lodun o kere ju. Obirin si le ma se ayewo foto ti a npe no mamografi (mammography).

Ipele Kansa Omu Obirin

A le se apejuwe bi aisan Kansa Omu ti tan ka inu ara si nipase ipele merin.

Ipele I (kinni): Koko omu ko tobi ju iwon sentimita meji lo

Ipele II (Keji): Koko ju iwon sentimita meji amo ko ju iwon sentimita marun lo. Aisan si ti tan si ora ti o wa ni abiya ti o sunmo omu ti aisan ti bere.

Ipele III (Keta): Eleyi pin si ona meji

Ipele IIIA: Koko ti o wa ni omu ju iwon sentimita marun, awon ibiti aisan yi si ti tan de ni abiya ti lepo mo ara won.

Ipele IIIB: Koko ti a wa ninu omu ti le mo awo ara, tabi koko yi ti je jabi bi ogbe lara omu, tabi o ti le mo igba aiya.

Ipele IV (Kerin): Eleyi ni igbati aisan yi ba ti tan kuro ninu onu lo si awon eya ara yoku.

Ipele kinni ati ikeji ni ibere aisan, nigbati o ba ti nde ipele keta ati ikerin, o ti wo ara gan niyen

Bawo ni a ti se nse itoju aisan yi

Ti aisan yi ba sese bere, eniyan le toju re nipase:

 • Ise abe – a o mu gbogbo omu tabi lara omu alaisan kuro. Anfani ati mu lara omu nikan kuro wa fun awon ti won ba tete wa si ile iwosan nigbati aisan yi ko ti wo ara.

 • Lilo ogun oloro (chemotherapy) – awon ogun yi a ma pa seeli ti ko dara lara, amo awon seeli miran ti won dara le faragba jamba nigbati a ba nlo awon ogun wonyi. Eleyi le mu inira ranpe wa. Awon ogun yi le bawa kapa awon kansa ti o ba ti tan lo si iha ara.

 • Yiyi eroja ara ti a npe ni homooni (Hormone) pada. Eyi a ma dena idagbasoke awon seeli ti o ba ti di kansa.

 • Ina oloro (Radiotherapy) – Ina yi lagbara pupo, o si le pa awon seeli ti won ba ti yirapada si Kansa.

A o ri wipe orisirisi ona ni a le gba se itoju aisan yi. Ona ti a o to, yio da le lori ibi ti aisan yi ba ti de ni inu iha ara, orisi itoju ti alaisan ba nfe, inawo, orisi irinse ti o wa ni agbegbe ti alaisan wa, ati oye lati tele ilana ti onisegun ba la sile. Itoju aisan kansa a ma na ni lowo a si ma gba opolopo asiko.

O dara ki alaisan ba awon omo ati molebi re soro nipa aisan yi. Alaisan yio si jere ife and iranlowo awon molebi nigbati awon tikarawon yio ni anfani lati le mojuto ara won ni ona ti o peye, ti won yio si dena aisan yi.

Ti aisan yi ba ti wora gan, awon ona ti a la sile yi na ni a o lo lati fi se itoju re. Amo ayori si itoju ko le dabi ti eniti aisan ko ti wo lara.

Kinni ayori si itoju aisan yi ti ri

Ayori si a ma yato lati alaisan kan si ekeji. Awon oun ti n’dari ayorisi ni wonwon yi:

 • Ibi ti aisan yi tan de ni iha ara

 • Iru aisan ti eleyi tile je. Larin awon aisan kansa omu, a ma nri iyato bi won ti se ni agbara si lara enikan si enikeji

 • Bi alaisan ba ti se tele ilana itoju onisegun si

Niwon igbati aisan yi ba si wa ninu omu nikan, ida mesan ninu ida mewa awon ti o ni aisan yi a si wa laiye lehin odun marun. Nigbati o ba ti lo si bi ona meji ninu ora abiya, eleyi a dinku si ida mefa ninu mewa. Ti o ba to ona mefa si mewa ti o ti tan si ni abiya, awon ti yio wa laiye lehin odun marun ko ni ju ida merin ninu mewa lo. Ni idi eyi, ose pataki ki alaisan le tete lo si ile iwosan.

Kiwa ni anfani ti o wa fun alaisan nigbati aisan yi ba ti wora? Nje eyi ko jasi wipe yangba ti fo! Niwon igbati emi ba si wa, ireti nbe. Ko si dokita ti o le so wipe, “ni igba bayi, ohun kan bayi yio sele si alaisan” nidi eyi, o ye ki alaisan si ma lo si ile iwon nitori wipe orisirisi ona ni awon dokita si le fi ran alaisan lowo, lati ri wipe ara ko nii.

Ipa wo ni eto ibile, adura tabi ise awo le ko ninu itoju aisan yi? Gbogbo eniti o nse itoju awon ti o ni aisan ni won ngba adura wipe, ki a ri ilana itoju ti yio bawa kapa re. Amo tit di a bi ti se nsoro yi, a ko ti ri. Eleyi ni o ma nmu alaisan miran sa soke sa sodo. O ye ki alaisan ni idaniloju wipe, ko si ilana miran ti o peiye ju eyiti a ka sile yi lo. Alaisan si le darapo mo iwadi (research ati clinical trials) gbogbo ti a se lati ni imo ti o peiye si lori aisan ti. Patapari re, e se dandan wipe ki alaisan tete wa si ile iwosan fun itoju!

Produced by

Professor Clement A. Adebamowo, Division of Oncology, Department of Surgery, University College Hospital, Ibadan, Oyo State, Nigeria

clement_adebamowo@yahoo.com

Close Window